
Oko Irese omo woyi ra
Woyi ra koma baara igba kigba
Igba kigba kanso lara
Oko irese omo woyi ra
Woyi ra koma baara eru keru
Eru keru abi lala lenu
Oko irese omo ajowu yo oko lenu
Oko irese omo aferu sana iyawo
Oko omo afowo ila reru omo afowo ikan ya iwofa
Oko je mi'le mi o ba teniwa, Ohun ti mo ba wa ju teni lo
Oko k'ema f'ago remi lekun, emon ni kie wa fi se tiwa
Oko irese omo boni rese bako ti ofin gba mo
Eyi to ti fin sile koma parun lailai
Edumare jowo bawa da Ilu Irese Si
Amin, Ase